Topic: Oro O! Awon Odaju Wo Ni Nwon Pa Awon Odokunrin Meji Yi Taofik ati Rafiu n’Ilorin?
Timeline: 2012-07-04 05:48:21
Lati Owo Idris Alooma, Ilorin ati Johnson Akinpelu, Abeokuta
Oro O! Awon Odaju Wo Ni Nwon Pa Awon Odokunrin Meji Yi Taofik ati Rafiu n’Ilorin?
BEEYAN ba jori ahun, to ba ri okan lara awon omoleewe meji kan, O·gbeni Taofik ati Rafiu tawon omo egbe okunkun pa n’Ilorin, yoo bu sekun ni nitori bi won se ge ori won lo raurau. Gege bi a se gbo, lale Ojoru,Wesde, to koja yii lawon kan sadeede bere si i yinbon lagbegbe Elekoyangan, n’Ilorin, tawon eeyan si bere si i sa kiri, iberu bojo si ba gbogbo awon to wa lagbegbe naa.
Lakooko isele yii, ko senikeni to le yoju ninu awon araadugbo naa nitori nise ni gbogbo awon eeyan naa n gbadura kikan-kikan.
A gbo pe lenu okan lara awon olugbe agbegbe yii pe o see se ko je pe awon adigunjale to fee wole awon omoleewe ohun sugbon ti won ko gba won laaye ni won yinbon pa won.
Sugbon ohun to ya awon eeyan lenu ni bi won se ge ori okan ninu won lo, ti won si pa awon mejeeji sinu agbara eje.
Ninu alaye enikan tisele ohun soju e, o lo pe tawon adigunjale ti maa n waa yo awon eeyan agbegbe naa lenu, ti won yoo si gba awon nnkan ini won lo pelu ibon, eyi to ti n mu ki iberu-bojo maa ba awon eeyan naa, n lawon mi-in se n so pe, o see se ko je adigunjale lo sose naa.
Lona mi-in, enikan to tun ba wa soro so pe o tun see se ko je awon omo egbe okunkun lo doju ija kora won. Awon kan so pe o see se ki ija lori obinrin waye laarin won, leyii to le fa ija ati ede aiyede ti won le fi para won. O ni nnkan to n ru awon eeyan loju ni bi won se ge ori okan ninu won lo, eyi to mu ki awon maa ro pe boya awon to fee fi setutu owo ni won.
Nigba ti a de ileewe Poli Kwara, won ni ko si alukoro won lofiisi, bee la pe nomba e, ko lo rara. Ohun ti a gbo ni pe o lo fun ise pataki kan. Leyin opo wakati, okunrin naa so pe isele yii ko waye ninu ogba Poli awon, o fi kun unpe ki i se awon omoleewe lo wa nidii oro iku naa.
Nigba ti a beere isele naa lowo alukoro awon olopaaKwara, O·gbeni Femi Fabode, o ni loooto nisele naa waye. Okunrin yii ni ko ti i senito yoju lati so pe oun mo awon eeyan naa ri. Fabode ni won ti gbokuu awon eeyan naa lo si Mosuari Osibitu Fasiti Ilorin, awon eka otelemuye si ti n ba iwadii won lo lori ohun tofa iku ojiji awon omoleewe naa.
Agunbaniro merin lo ku nipinle Ogun lasiko ti won nsin ile baba won -- Johnson Akinpelu, Abeokuta
Niluu Abeokuta ni alakooso fawon agunbaniro nipinle Ogun, Agbejoro Theresa Anosike ti salaye laipe yii pe merin ninu awon agunbaniro ti won n sinjoba nipinle naa ni won padanu emi won, won ko le ba awon elegbe won pari ise isinlu ti won waa se nipinle naa.
O soro yii lakooko ti won n sayeye idagbere fawon owo keji ti won sese pari isinlu won, eyi to waye ni Papa Isere MKO, ni Kuto. Bakan naa lo so pe mejila ninu awon bii egberun meta le leeedegbeta ni won ko ni i ba awonyooku won gba iweeri nitori awon aisedeede kan ti won se. Meta ninu awon agunbaniro mejila naa lo je pe won ti fosu meji si merin kun igba ti won yoo fi se agunbaniro won,nigba tawon mesanan yooku yoo tun sese bere eto tiwon.
Anosike tun te siwaju pe meta ninu won ni won fun ni awoodu pelu iwe-eri fun ipa ribiribi ti won ko lakooko ti won fi n sin orileedebaba won. O waa gbadura fawon ti won se aseyege naa pe ki Oùlorun maa tele won lo sibi gbogbo ti won ba n lo.
Ninu oro Gomina Ibikunle Amosun nibi ayeye naa, o gba awon agunbaniro ohun nimoran lati ri i pe won ko lo gbogbo akoko ti won fi n sinijoba naa lasan, ki won wa ona ti won yoo fi maa da ise se lai gbekele ijoba. O ki won ku oriire fun bi won se se aseyege, o si ro won lati ma se gbagbe awon iriri ti won ti ni lakooko naa.
Bakan naa lo so pe ki won ri i pe won je asoju rerenibi ti ori ba gbe won lo, ki won si maa sa fun awon nnkan to le ba won loruko je. Amosun waa seleri pe gbogbo ona nijoba oun yoo fi maa te siwaju lati ri i pe idagbasoke ati ipese ise wa fawon odo. Lara awon eto to waye lojo naa ni yiyan bii ologun, eyi ti won fi se idagbere fawon eeyan ipinle Ogun.
**{Legacy activities, comments etc counter: 611; topic series: 12; forum: MediaYoruba; associated: 12- /*}