Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Aburú Ìsọ́tá-Ìsìláàmù Islamophobia, Ogun Ìpayà àti Ìbi Zionism

Pada si "Àwọn Aburú Ìsọ́tá-Ìsìláàmù Islamophobia, Ogun Ìpayà àti Ìbi Zionism"

Àwọn Aburú Ìsọ́tá-Ìsìláàmù Islamophobia, Ogun Ìpayà àti Ìbi Zionism
NewsTeam
Awọn ifiweranṣẹ: 12
Ẹ darapọ̀: Ọjọ́bọ̀ Nov 06, 2025 6:47 am
Olubasọrọ:

     NewsTeam Awọn ifiweranṣẹ: 12    Ẹ darapọ̀: Ọjọ́bọ̀ Nov 06, 2025 6:47 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ NewsTeam »

Esin122 Bello Turji Ògbóǹtarìgì Agbésùnmọ̀mí Ti Jáde Sọ̀rọ̀, Ó Ní Òun Kò Gba Mílíọ́nù Owo Lọ́wọ́ Ìjọba Tàbí Ẹnikẹ́ni

Ìjọba ló dalẹ̀ wa

Láti ọwọ́ Adeola Olanrewaju

Ògbóǹtarìgì agbésùnmọ̀mí tó ń da ìpínlẹ̀ Zamfara, Sokoto àti agbègbè láàmú ti jáde sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun gbà-má-bínú tí ìjọba ní òun fún òun àti ikọ̀ rẹ̀.

Bello Turji ní òun kò gba mílíọ́nù mẹ́ta náírà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fún òun ní ọkọ̀ kankan o. Lóòóọ́ ni àwọn aṣojú ìjọba bá àwọn ṣe ìpàdé àmọ́ wọn kò fún àwọn ní nǹkankan, bí òun ṣe wà yìí, òun kò dá ní mílíọ́nù márùn-ún náírà lápò.

Ọ̀rọ̀ yìí ni èsì sí ọ̀rọ̀ tí aṣojú ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara lọ́dọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí; Musa Kamarawa sọ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara ìgbà náà fún Bello Turji ní mílíọ́nù mẹ́ta nạírà àti ọkọ̀ bọ̀gìnì láti ti ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ.

Muhammad Matawalle ni gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara nígbà náà òun sì ni mínísítà fún ètò ààbò nísìn yìí.

Bello Turji ní òun fi orúkọ Allahu búra pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ òun wọn kò fún òun ní kọ́bọ̀ tàbí ọkọ̀ kankan, kódà, òun kò dá ní owó tí iye rẹ̀ tó mílíọ́nù márùn-ún náírà. Gbogbo ohun tí a ń ṣe kìí ṣe nítorí àpò tiwa, kò sí tiwa gan-an nínú ohun tí a ń ṣe wọ̀yìí.

Ó fi ẹ̀sùn kan Kamarawa pé ó dalẹ̀ àdéhùn wọn nígbà ìpàdé àlàáfíà náà, gbogbo ohun tí o ní oó fún wa ni a kò rí tó sì tún wá parọ́ pé a gba owó àti ọkọ̀.

Inú wa kókọ́ dùn nígbà tí ìjọba Zamfara yàn ọ́ ní agbódegbà wa nítorí pé a rò pé o ó ṣe tiwa àmọ́ ìwà ọ̀dalẹ̀ ni ó hù, o kò fún wa lówó kankan ó sì tún wá parọ́ pé o fún wa.

Gbogbo ohun tí a ń ṣe kò ní ọwọ́ ìṣèlú nínú bí àwọn èèyàn ṣe rò bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìmọtara-ẹni-nìkan nínú rẹ̀, àwọn ń ṣe ti àwọn fún Allah ni.

Bákan náà ló dá ìjọba lẹ́bi ètò ààbò tó mẹ́hẹ, ó ní gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto tẹ́lẹ̀’ Attahiru Bafarawa àti gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ́lẹ̀; Ahmed Yerima ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbésùnmọ̀mí kí Matawalle tó tẹ̀síwájú níbi tí wọ́n bá a dé.

Bello Turji ní Allah ni ẹlẹ́rìí òun lórí gbogbo oghun tí òun sọ yìí.

Àwọn ará Sokoto kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ dànù, wọ́n ní ọgbọ́n àti ète lórí ìdìbò ọdún 2027 ni gbogbo èyí tí ìjọba ń sọ tí Bello náà ń fèsì, wọ́n ní ọgbọ́n àti pín àwọn yẹ́lẹyẹ̀lẹ kí ìdìbò tó dé ni wọ́n ń dá pé kò sí èdè àìyedè láàrín wọn rárá.

Alhaji Sani Aliyu; ẹni tó jẹ́ adarí ìletò kan ní Sokoto ní kí ẹ má dá àti ìjọba àti Bello Turji lóhùn, eré ìtàgé ni wọ́n ń fi ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣe, mẹ̀kúnnù ń kú lójoojúmọ́ nígbà tí àwọn olówó ń jiyàn ẹ̀bi.

Malam Abdullahi Bello náà sọ̀rọ̀, ó ní kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé ọgbọ́n ìdìbò ọdún 2027 ni wọ́n ń dá tí wọn fi ń sọ gbogbo èyí, lọ́gán tí wọ́n bá dé ipò tán ni ìfẹ̀míṣòfò ó tún burẹ́kẹ síi.

Gbogbo ohun tí Bello Turji sọ yìí kò ní kí ilé iṣẹ́ ológun ó yọ orúkọ rẹ̀ kúrò nínu àwọn agbésùnmọ̀mí. Bello jẹ́ ògbóǹtarìgì agbésùnmọ̀mí tí àwọn ológun ti fi orúkọ rẹ̀ síta tipẹ́ pé àwọn ń wá a.

Àwọn itú wo ni Bello Turji ti pá?

Ọjọ́ kẹta ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni a gbọ́ pé Bello ránṣẹ́ ìdúnkokò sí àwọn ará Sokoto pé kí wọn ó kúrò ní ìlú wọn ní kíákíá kí wọn ó wábi gbà lọ.

Ó fi lée pé òun ń bọ̀ wá pa gbogbo wọn bí wọ́n bá kọ̀ tí wọn ò lọ.

Àwọn ará agbègbè yìí ti wá ké gbàjarè sí ìjọba pé kí ìjọba ó gba àwọn lọ́wọ́ Bello Turji yìí o, wọ́n ní ìdúnkokò yìí kò jọ àwàdà rárá, ohun tí yóò ṣe ló ti sọ yẹn o.

Abubakar Isa; ọ̀kan nínú àwọn ará àdúgbò náà wí pé ó ṣeni láàánú ò sì tún bani lọ́kàn jẹ́ àwọn àrè àtọ̀húnrìnwá ni wọ́n ń pàṣẹ fún àwọn onílùú pé kí àwọn ó kúrò ní ìlú àwọn.

Àwọn ará agbègbè náà ṣe àlàyé pé inú fu àyà fu ni àwọn wà láti ìgbà tí Bello Turji ti ránṣẹ́ náà nítorí pé ìgbàkúùgbà ni ó le dé bí ó ṣe sọ. Wọ́n ní àwọn ó le fi ilé àti ọ̀nà àwọn sílẹ̀ sá lọ fún àwọn àlejò tí wọ́n ń ṣe àwọn báṣubàṣu. Wọ́n wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti gba àwọn kalẹ̀.

Ipa àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Turji

Ó lé ní ọgọ́rùn-ún àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Bello Turji tó dágbére fáyé nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ Zamfara kóra jọ tí wọ́n sì ṣe ìkọlù sí ibùdó wọn.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù yìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà kóra jọ láti ṣe ìkọlù sí ibùdó Bello Turji kí wọn ó le mú un lókú tàbí ààyè. Àmọ́ Bello Turji ti rí ẹni ta á lolóbó nípa èyí, ẹgbẹ̀rún àwọn agbésùnmọ̀mí ló kó wá sí ibùdó náà ní kíá mọ́sá, ìjà náà gbóná janjan láàárín àwọn méjéèjì, ìbọn ń ró lákọlákọ.

Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, ó lé ní ọgọ́rùn-ún àwọn omọlẹ́yìn Bello Turji tó kú nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó kú lé ní ogún.

A gbọ́ pé Bushari Meniyo; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ agbésùnmọ̀mí àmọ́ tó ti ronú pìwàdà ló ṣaájú àwọn ẹ̀ṣọ́ ìbílẹ̀ náà láti lọ kojú Bello Turji. Bushari wà lára àwọn tó bá ogun náà lọ.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà wí pé àwọn ológun kò yọjú rárá fún gbogbo wákàtí tí àwọn fi jagun náà, wọ́n ní bí ó bá ṣe pé àwọn ológun wá ran àwọn lọ́wọ́ ni, àwọn kò bá rí Bello Turji pa lọ́jọ́ náà.

Fi èsì kan ranṣẹ

Bello Turji Ògbóǹtarìgì Agbésùnmọ̀mí Ti Jáde Sọ̀rọ̀, Ó Ní Òun Kò Gba Mílíọ́nù Owo Lọ́wọ́ Ìjọba Tà



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Aburú Ìsọ́tá-Ìsìláàmù Islamophobia, Ogun Ìpayà àti Ìbi Zionism"

Fún Ìdáhùn