Topic: Ki Lo Fa Ariwo To To Bayii Na, Oga Olopaa Patapata: Olopaa To Ba Ti Gbegi Dina, E Waa Fejo Re Sun Wa — Komisanna Olopaa Osun
Timeline: 2012-07-04 05:45:10
Lati Owo Bisi Adewoye, Ilesa
Ki Lo Fa Ariwo To To Bayii Na, Oga Olopaa Patapata: Olopaa To Ba Ti Gbegi Dina, E Waa Fejo Re Sun Wa — Komisanna Olopaa Osun
O·ga olopaa patapata seun to ni oun ko ni i je ki awon olopaa pada soju titi mo. O·loun nikan lo mo idi ti ariwo fi po to bayii lori oro pe kawon olopaa ma gbe igi dana mo, ki won ma duro si oju titi lati gbowo lowo onimoto, kiwon yee gbe iro kale pe awon n seto aabo kan lawon se wa loju ona, ki won je ki awon onimoto rin geere. Gbogbo ariwo yii fi han pe ona ofun ona orun ni, awon ti won n jeun nibe funra won ni won wa nidii oro yii, awon olopaa gan-an lo n de awon araalu sijoba.
Won saa fe ki ijoba ati oga olopaa patapata da kinni naa pada, ki awon olopaa maa wa loju ona, nitori owo ti won n pa nibe ko kere, latiori oga desale ni won si jo n pin in.
Ohun to n yaayan lenu ni pe opo awon ti won n pariwo pe ki won je kolopaa pada si oju titi yii, opolopo won ni won n rin kaakiri awon orile-ede agbaye, awon naa ko si le so pe awon ri i nibi kan ti awon olopaa yoo ko ara won jo, ti won yoo so pe awon n ye iwe moto wo, afi orile-ede ti won ba ti n jagun lowo,tabi ti nnkan aburu kan ba sele lojiji.
Sugbon ti Naijiria yii ko lojo, ko losu, ojoojumo ni.
Awon olopaa yoo gbe moto won jade ni kutukutu owuro, won yoo se bii eni to n lo si soobu oja tita, nigba ti won yoo ba si fi de lale,awon pelu obitibiti owo ni. Se eyi la o maa se lojoojumo. Loooto ni wahala wa, awon odaran po niluu nitori aburu orisiirisii to n ba Naijiria, bi awon olopaa ba si wa loju ona, o see se ki iwa odaran yii dinku. Sugbon awon olopaa tiwa ko ri bee, opolopo won ni won n ran awon ole lowo, awon mi-in si je ole funra won. Bi ole ba n ja ni maili kan pere si ibi ti awon olopaa yii gbegi-dana si, bi e ranse pe won won ko ni i dahun, won le so pe awon ko ni ibon tabi ki won ni moto awon ko dara, ki waa ni idi ti won fi wa loju titi naa gan-an.
Bi awon olopaa mi-in ba gburoo awon ole yii ti won n yinbon bo, won yoo fese fe e lesekese ni, o si digba ti awon ole naa ba lo tan ni won yoo be ja titi, ti won yoo maa fun fere adamodi kiri igboro. Ko seni ti yoo so pe oun ko mo pe ohun ti ogunlogo awon olopaa oju ona yii n se niyi, ko si seni ti yoo so pe oun ko mo pe iwa odaran lona marose dinku ju bo ti se wa tele lo. E wa ona miin ti awonolopaa yoo fi maa seto aabo loju popo, e ma je ki won gbegi dana mo o.
Olopaa to ba ti gbegi dina, e waa fejo re sun wa — Komisanna olopaa Osun -- Bisi Adewoye, Ilesa
L ojoru, Tosde, ose to koja yii ni O·ga olopaa ipinle O·sun, Arabinrin Kalafite Adeyemi fi da awon eeyan loju pe wahala adingunjale atawon iwa miiran to fara jo o yoo dohun itan nipinle naa, paapaa julo niluu Ilesa ati agbegbe re.
Adeyemi soro naa nigba to sabewo mo-mi-nmo-o siluu Ilesa, Gege bo se so, o ro awon araalu lati maa foro awon ti won ba keefin lawujo pe irin won ko mo to awon olopaa leti. Obinrin naa ni gbogbo oro ti won ba so fawon lawonyoo fi se bonkele, awon yoo si gbe igbese to ba ye. O tun fi da awon araalu loju pe ofin ti oga olopaa patapata l’Abuja fi lele lori gbigbe igi di oju ona lawon yoo ri i pe o fidimule. O ni ti awon araalu ba ri olopaa to ba n hu iru iwa bee, ki won fi to oga olopaa Ilesa, O·gbeni Kayode Turner leti fun ijiya to ye.
Ninu oro i f o k a n b a l e tobinrin naa so, o ni pelu oko ayeta meji toun fi ranse siluu naa, ileese awon yoo ri i pe idigunjale to n fojoojumo sele nibe dohun itan.
**{Legacy activities, comments etc counter: 668; topic series: 11; forum: MediaYoruba; associated: 11- /*}