Topic: Owo Awon Agbofinro Te Arabririn Ti O Ko Opolopo Kokeeni Sodo Abe: Ole Lo Pa Ogbeni Onimoto Kan To Gbe Kokeeni Tikokeeni
Timeline: 2012-07-04 05:55:06
Lati Owo Ademola Adejare
Owo Awon Agbofinro Te Arabririn Ti O Ko Opolopo Kokeeni Sodo Abe: Ole Lo Pa Ogbeni Onimoto Kan To Gbe Kokeeni Tikokeeni
Arabirin Fadina ki opolopo kokeeni sinu abe e, owo ajo NDLEA ti te e IYALE›NU nla ni oro iyaale ile kan ti won pe oruko e ni Fadina Bala si n je fun gbogbo
awon to gbo pe obinrin naa gbe oogun oloro soju arare.
Bo tile je pe ki i se igba akoko niyi ti awon eeyanyoo gbe oogun oloro, eleyii ti obinrin wa ninu won, ijoloju to wa ninu tie ni pe oun leni akoko ti yoo gbe oogun oloro to po ju si oju ara.
Idi merindinlaaadorin la gbo pe obinrin eni odun mejidinlaaadota naa gbe si oju ara re. Ilu Nairobi, lorile-ede Kenya ni omobinrin naa n lo ki owo ajo to n gbogun ti oogun oloro too te e ni papako ofurufu ile wa ni ose to koja.
Agbenuso ileese ajo NDLEA, Ogbeni Mitchell Ofoyeju so fawon akoroyin lose to koja pe latigba ti ileese naa ti bere lodun 1989, obinrin yii ni yoo je eni akoko ti yoo gbe oogun oloro to po to bee si oju ara.
O so pe o di oogun naa sinu ara e debii pe ko le rin daadaa mo. Nigba ti asiri e yoo si papa tu, bo se bere pe ki oun mu eru re to ja bo sile niokan ninu idi kokeeni naa ja bo lati idi re, n loro ba pesi je.
Orile-ede Australia la gbo pe omobinrin naa to kekoo jade ni Yunifasiti Obafemi Awolowo n gbe tele, odun meji lo lo nibe ko too di pe awon alase ibe da a pada sile.
Nigba to n soro, o ni idi toun fi gbe oogun oloro naa ni ki oun le rowo ileewe omo oun san, koun si tun le ri owo lanloodu ile oun, to ti n le oun kiri, to si n leri pe oun yoo da eru oun sita ninu osu to n bo bi oun ko ba sanwo naa.
Fadina ni idi toun fi ko oogun naa soju ara ni pe oun ko fee ku nitori oun ti gbo nipa isele awon eeyan ti oogun naa ti be si ninu.
Ole lo pa a: ogbeni onimoto kan to gbe kokeeni tikokeeni
Se e ti gbo ti ogbeni onimoto kan to gbe kokeeni tikokeeni naa si fo mo on ninu, to ran an lo sorun kiakia. Lese kan naa lo ku o, bi a si ti n wiyii, koda ko se pe o n rakoro ni, yoo ti yo siluu orun.
Bi nnkan bayii ba sele, awon eeyan ki i mo iyato ninu iku to n pa oloju kokoro ati ole eniyan, yato si iku to n pa eni ti ebi n pa. Bi awon kan ba ti gbo pe kokeeni fo mo eni kan ninu, won yoo sare so pe ebi lo n pa a, iya lo n je e, bi ki i baa se pe ijoba ko fun un nise ni, ko le gbe kokeeni.
Ko soro gidi kan ninu iyen. Idi ni pe awon ise buruku kan wa ti ebi ko le paayan de idi e. Eni ti kokeeni fo mo ninu yii, dereba ni o, bee lo nise lowo to n se. Sugbon nigba ti won waa ba a pe yoo di olowo nla, yoo di olowo repete, o gba lati gbe kokeeni, ibe naa lo si ba lo sorun.
Ebi ko lo n pa iru eni bayii, ole oju lo n yo o lenu. Owo kekere ko ni won fi n lo siluu oyinbo, owo ti eniyan yoo fi wo eronpileeni leekanyoo to lati da bii eni meta merin lokoowo olowo pooku. Sugbon awon eeyan wonyi ko fee sise ni, won feran lati ni owo lasan ni, owo to po ati owo ojiji, ki won si maa sako sawon elegbe won ati awon aladuugbo won pe owo awon ti de, lai ni i so ise tawon n se fenikan. O·to ni ebi o, oto ni ise, oto si ni ole oju ati ojukokoro.
Eni ti nnkan kekere ko ba ti to, ko si kiru won ma di odaran, ko si ki won ma siwa-hu, bi oro won si se maa n ri rederede naa niyi. Ki eniyan ma puro mo ise, ko so pe ise n se oun ni, ko ma puro mo osi, ko so pe osi n ta oun ni, eni ti ko ba nise ko wa ise, eni to ba si ti nise kan to n se lowo ko tera mo on. Idi ise eni la ti i mo enilole, ise teeyan ba si n se ti ko siwo naa ni yoo so o di oloriire. Bi e ba ni omode ki e kilo fun won o, bi e ba si ni agbalagba ti ojukokoro naa n yo lenu e ba won soro, ohun to n seku pa ni ko to nnkan, diedie loruko eda si n baje, eni to ba se e yoo foju ara re ri i.
**{Legacy activities, comments etc counter: 626; topic series: 5; forum: MediaYoruba; associated: 5- /*}