Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 101 from MediaYoruba
Topic: Ijanba Baalu Ni Ilu Eko: Ariwo Iranu Ti Won Yoo Maa Pa Niyen O - Ohun Ti E Oo Gbo Lenu Jonathan Niyen
Timeline: 2012-07-04 05:26:34


Lati Owo Alabi Adeola, Ile Igbimo

Ijanba Baalu Ni Ilu Eko: Ariwo Iranu Ti Won Yoo Maa Pa Niyen O - Ohun Ti E Oo Gbo Lenu Jonathan Niyen

Bi ijamba ba ti sele bayii, ariwo lotun-un, ariwo losi le o maa gbo. Ijoba yoo so pe oun ti gbe igbimo kan dide, won yoo so pe awon gbodo mo ohun to fa sababi isele naa. Kia bayii lawon kan yoo ti bo sita, won yoo so pe eronpileeni naa ko dara rara, ko tile ye ko maa rin loju ona wa.

Won tile le so pe awon ti fi ofin de iru eronpileeni bee pe ko gbodo rin, O·loun lo mo eni to tun gbe e sita. Won yoo waa se ileri fun gbogbo omo Naijiria pe awon yoo wa eni to fun won lase iru e, awon yoo fi ofin de eronpileeni naa ti ko fi ni i rin nibi kankan ni Naijiria mo. Won yoo so pe ohun ti awon nduro de bayii ni iwadii ti awon igbimo ti awon gbe dide n se, bi won ba ti pari iwadii naa, awon yoo mu ise se kiakia ni. Ohun ti yoo waa buru ni pe alo ramirami lawon eeyan yoo ri, ko senikan ti yoo ri abo re, ibi ti oro naa yoo pin si niyen.

Eni kan ko le mo iru iya ti won fi je ileese naa, tabi esi iwadii ti awon eeyan naa se.

Nidii eyi, ko too di ojo meloo kan, eronpileeni naa yoo tun pada soju ona, leyin ti won ba ti ha awon awodi-jeun-epe-sanra ti won wa nileese ijoba lowo repete. O·po awon eronpileeni ti won wa ni ile tiwa nibi ni wonti fofin de niluu oyinbo, won ko tile gbodo ri ohun to jo o.

Sugbon awon eronpileeni yii ni awon eeyan tiwa yoo loo kun loda, ti won yoo fi owo ra a, ti won yoo gbe wa sibi, ti won yoo so pe tuntun ni.

Iyen la se n ku pepepe bii adie, iyen lo se je pe ni gbogbo agbaaye loni-in, Naijiria ni eronpileeni ti n ja leralera julo. A ko ni oga ninuijamba oju orun rara.

Ohun ti e oo gbo lenu Jonathan niyen

Aare ile wa ti kede pe ojo meta la o fi maa daro, ojo meta la o fi maa sunkun, nibi gbogbo ta a ba wa, ko si aye ariwo, afi ka maa sunkun, ka si maa daro awon eni wa to ku sinu ijamba, awon eeyan wa to ku sidii iranu tijoba ta a ni n se.

Sebi to ba je awon eeyan tiwa nibi yii n se rere ni, to ba je ijoba tiwa dara bii ijoba awon orile-ede to ku, yoo soro ki eronpileeni tiwa too maa ja bo poo poo bayii bii ologbo ti ko lounje ninu. O·ro ti Jonathan maa n so,ati ejo to maa n ro bi ijamba ba ti ba wa ni Naijiria ti to, o ti su awon omo Naijiriapaapaa, won ko fe mo. Ohun ti won fe ni ko wa ojuutu si oro naa, ko si tan isoro gbogbo aburu ti n sele yii o. Awon nnkan kan wa ti apa ijoba le ma ka, sugbon ki i seiru awon nnkan bawonyi.

Bi apa ijoba kan ko ba ka awon eleyii, oku ijoba pata gbaa ni, ko si le mu nnkan rere kan wa fun awon ara ilu re. Ma fi oko mi se ona mo,sebi ojo kan la n sofin re. Bi awon ti won n fi eronpileeni sise lati ile okeere ko ba le gbe eyi to dara wa, tabi ti won ko ba le se atunse si awon oko ofurufu to ba baje, ki ijoba Naijiria yee faaye gba won, ko ye ki won je ki won ko won duro nile yii rara, bee ni ko ye ki won fi aaye gba won lati ko omo Naijiria kankan.

Sugbon ijekuje, iwa ole ati wobia to ti po ninu awon ti won n sejoba ile yii, atawon ti won n pe ara won ni osise ijoba ki i je ki iru eyi see se ni Naijiria, eni ba ti lowo lowo, tabi to mo awon eeyan, koda ko maa gbe posi kiri ko pe e ni eronpileeni, awon alase Naijiria yoo yi oju won segbee kan bii eni pe won ko ri i ni, oun lo dele yii o.

Eyi ni awon ijamba eronpileeni Baalu to ti sele ni Naijiria

IGBA merindinlogun ni ijamba oko ofurufu ti sele nile wa, ogunjo, osu kokanla, odun 1969 nijamba oko ofurufu akoko sele l’Ekoo, eeyan metadinlaaadorun-un lo ku nibe.

Leyin eyi ni okan naa tun sele lojo kejilelogun, osu kin-inni, odun 1973 ni Kano, eeyan mokanlelaaadosan-an lo ku ninu eleyii, Meka ni baalu naa ti n gbe won bo.

Omi-in tun sele lojo kin-in-ni, osu keta, odun 1978, baalu ile wa niyen, eeyan merindinlogun lo padanu emi won si i ni Kano, ko too di pe omiin tun paayan metalelaaadota lojo kejidinlogbon, osu kokanla, odun 1983 nitosi Enugu.

Odun 1991 ni Naijiria tun gburoo isele ijamba oko ofurufu, ojo kokanla, osu keje leyi sele, ilu Jeddah lawon eeyan naa ku si. Otalelugbao-le-kan eeyan lo ku sinu eronpileeni yen, ko si pe naa, iyen losu kesan-an, odun 1992 tomi-in tun fi sele, igba eeyan lo ku sinu iyen, Eko ni baalu naa ti n bo.

Ijamba yii tun sele lodun 1995, 1996, 1997, odun 2000 ati 2002. Eyi tawon eeyan ko le tete gbagbe ni todun 2005, oko ofurufu to n bo latilu Pota lawon omoleewe bii aadota pare sinu e labule Lisa nitosi Ijoko, nipinle Ogun.Bakan naa nisele aburu mi-in tun waye ninu osu kesan-an, odun 2006 ni Benue, ti obaile Sokoto padanu emi e.

Ohun kan to han gbangba ni pe tose to koja yii lawon eeyan si padanu emi won ju, latigba ti baalu si ti n ja nile yii, ko ti i ja sinu ile ri, nitori naa nijamba yii se kale-kako.


**{Legacy activities, comments etc counter: 1054; topic series: 12; forum: MediaYoruba; associated: 12- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Ijanba Baalu Ni Ilu Eko: Ariwo Iranu Ti Won Yoo Maa Pa Niyen O - Ohun Ti E Oo Gbo Lenu Jonathan Niyen



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn