Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 108 from MediaYoruba
Topic: Ore Awon Egbe Onimoto Soro O Se, E Tete Ba Ajimobi Soro
Timeline: 2012-07-04 05:36:37


Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Ore Awon Egbe Onimoto Soro O Se, E Tete Ba Ajimobi Soro

Oloun nikan lo mo ohun to maa n se awon ti won ba n se gomina Ipinle Oyo to se pe bi won ko ba ti i ba awon egbe onimoto se, ara won kii ya gaga. Boya won ko si mo pe ki i se awon onimoto lawon n ba se yen, pe egbe awon ogaAgbero lawon n mu loree ni.

Gbogbo awon ijoba ti won ti mu awon oga Agbero yii loree, sebi abuku ati ete ni won n kan nigbeyin, ohun to si maa n je ki won da Ibadan ru nigba ti won ba bere wahala won ni yen. Bi ijoba ba fee ba awon onimoto ipinle Oùyo soro, ki won wa ona mi-in, ki won ma si se gbe¯ seyin enikeni bi oro ba wa bo se wa yii.

Tokyo wa nibi kan to n so pe alaga egbe onimoto ni oun, ijoba Ajimobi n ko awon mi-in kiri pe awon ni alaga, kerekere, iru oro yii yoo tun bimo kan. Ohun to daju saka ni pe oro naa ki i bimo rere, bi ko bi kumo, yoo bi kondo, tabi ko bi ki won tun maa yinbon pa ara won kiri. Bi a ba n ba ole wi, ka kilo fun awon onisowo eba-ona, bi won ba n so pe awon onimoto n se jagidi-jagan, kijoba paapaa yee kowo fun won tabi ba won se nitori oro ibo, nitori lojo tina ba feju, ina paapaa ki i mo oju eni to da oun o.

E so fun Gomina ko sora loju ona to n to yii o, LamAdesina ti to o ri, Rasidi Ladoja ti to o ri, Alao Akala sese to o koja ni, ko senikan tori iroyin ayo mu bo nibe, afi iroyin kikan nikan. Aabo oro...

Lori esun iparogbowo, onisowo moto foju bale-ejo niluu Osogbo

O›KUNRIN kan, Lanre Ojo, eni odun metadinlaadota ni won fesun kan pe o gbowo to je milionu meji ati egberun lona irinwo naira (N2.4million) lowo awon osise oba meji.

Awon osise oba mejeeji ohun, Ogbeni Adegboyega Opeyemi ati Anthony Iyiola Fabure ti won je olupejo, je osise nile-ekose isegun oyinbo LAUTECH, iyen Ladoke Akintola University Teaching Hospital, to wa niluu Osogbo. Agbo pe Lanre seleri lati ba won ra moto wale lati orile-ede Canada to fi se ibugbe.

Gege bi agbejoro fun ileese olopaa se so, ore awonolupejo kan to ti doloogbe bayii lo mu won mo olujejo, idi si niyi ti won fi kowo naa funun. Adehun won ni pe ki okunrin naa ba won ra moto EOD Honda Accord ati Nissan Central Car, 2004 model, sugbon eti lobinrin fi n gbo ohun oro lo foro naa se fun won.

Agbejoro fun ileese olopaa, Inspekito Akingbade Sunday, salaye pe latinu osu kewaa, odun 2011, lawon olupejo ti kowo naa fun olujejo lagbegbe Dada Estate, niluu Osogbo, to si seleri fun won pe oun yoo ba won gbe awon moto naa wa sugbon ti ko se bee. Leyin tawon eeyan yii duro fun osu meta ti won ko gburoo owo, bee niwon ko ri moto ni won loo foro naa to ileese olopaa leti, lati igba naa si ni won ti n waOgbeni naa kaakiri ko too di pe owo te e laipe yii.

Akingbade salaye fun ile-ejo pe iwa ti Lanre Ojo hu naa lodi, o si ni ijiya nla labe ofin orile-ede yii todun 2006. Sugbon nigba ti won ka esun kansoso ti won fi kan Ojo si i leti, ti won si beere boya o jebi tabi ko jebi, o ni oun ko jebiesun naa.

Bakan naa ni agbejoro re, Asheem Abioye, ro ile-ejo pe ko faaye beeli sile fun onibaara oun, ati pe ko ti i si eri aridaju pe Lanre jebi esun ohun, ayafi ti idajo ba so bee. Agbejoro fun ileese olopaa ta ko arowa agbejoro olujejo naa pelu alaye pe okunrin naa ko ni adireesi kan pato teeyan le wa a si niluu Osogbo, ati pe lakookoto n gbiyanju lati sa lo sorile-ede Canada lowo awon olopaa te e.

Adajo ile-ejo naa, Adewunmi Makanjuola gba beeli okunrin yii pelu milionu meji naira ati elerii meji ni iye kan naa. Makanjuola waa sun igbejo siwaju di ojo kerindinlogbon, osu keje, odun yi.


**{Legacy activities, comments etc counter: 606; topic series: 7; forum: MediaYoruba; associated: 7- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Ore Awon Egbe Onimoto Soro O Se, E Tete Ba Ajimobi Soro



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn