Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 116 from MediaYoruba
Topic: Adebimpe Atore E Lu Ogbeni Hausa Abdulraheem Amadu To N Sewo Ni Jibiti l’Osogbo: Owo Olopaa Ti Te Segun To N Se Gbaju-e Ni Ilorin
Timeline: 2012-07-04 05:50:43


Lati Owo Florence Babasola, Osogbo ati Idris Alooma, Ilorin

Adebimpe Atore E Lu Ogbeni Hausa Abdulraheem Amadu To N Sewo Ni Jibiti l’Osogbo: Owo Olopaa Ti Te Segun To N Se Gbaju-e Ni Ilorin

Adebara Adebimpe ti foju ba ile-ejo Majisireeti iluOsogbo bayii lori esun pe o lu mola kan ni jibiti owo to to egberun lona oodunrun naira.

Adebimpe ni won fesun kan pe oun ati ore re kan lu okunrin Hausa naa, Abdulraheem Amadu ni jibiti lojo kejilelogun, osu karun-un, odun yii.

Gege bi agbejoro fun ileese olopaa, Inspekito JohnIdoko se so, se ni Bimpe pelu enikeji re so fun Amadu pe awon fee paaro owo dola ile okeere to to egberun meji. Nigba ti Amadu ko owo ile yii fun ore Bimpe, to si ku kawon omobinrin naa ko owo dola owo won sile niyen se bii eni pe oun fee gba ipe lori ero ibanisoro re legbee kan, sugbon se lo na papa bora, latigba naa ni won ko ti gburoo re mo.

Bayii ni Adamu fi olopaa mu Bimpe, ti oro re si de kootu. Nigba ti won ka esun jibiti lilu ati ole jija tileese olopaa fi kan Adebimpe si i leti, o loun ko jebi awon esun naa.
Agbejoro fun Bimpe, John Olabinjo ro ile-ejo lati faaye beeli sile fun olujejo lona to rorun, o si seleri pe ko ni i sa lo. Agbejoro fun ileese olopaa ta ko arowa olujejo, o ni
niwon igba ti enikeji re ko ti yoju, o le di iwadii to muna doko lori esun naa lowo.

Sugbon Adajo Olusola Aluko so pe ohun ti agbejoro ileese olopaa so lori beeli olujejo ko lese nile, nitori naa lo se fagile e.

Olusola waa gba beeli olujejo pelu egberun lona igba naira ati elerii meji ni iye kan naa.

Leyin naa lo sun igbejo si ojo kokandinlogbon, osu keje, odun yii. Nigba ti Bimpe n salaye oro yii, o ni aaro ojo naa loun pade ore oun to ti sa lo ohun, ati pe se lo seleri lati
ba oun wa ise.

O nigba tawon de agbegbe Sabo lo so foun pe oun ni awon owo ile okeere toun fee paaro lodo Hausa si owo naira, o si ni kawon jo ya sibe, o loun ko fura pe ero buburu wa ninu omobinrin ohun lojo naa.

Owo olopaa ti te Segun to n se gbaju-e ni Ilorin -- Idris Alooma, Ilorin

PAKO bii eran to bo sinu takute lokunrin kan, Ogbeni Segun Abayomi towo te laipe yii niluu Oro, nipinle Kwara pe o lu obinrin kan ni jibiti egberun kan dola n wo, bowo seee te e ni won ti ju u satimole ogba ewon.

Segun, eni odun mejidinlaaadota la gbo pe o n gbe agbegbe Oke-Ola, niluu Oro. Esun ti won fi kan an ni pe o gbimo po sise ibi, bee lo tun se gbaju-e fobinrin kan, Arabinrin Thomas Oyebola Abiodun, to n gbe lagbegbe lrewolede, n’Ilorin, pelu egberun kan dola to loo gba ni banki. A gbo pe nise lo gbimo po pelu okunrin kan to n je Kayode, eni ti ko ni adiresi kankan to si fi gbaju-e gba egberun kan ati eedegbejo egberun-un naira miin.

O ti se gbogbo nnkan naa tan kiye okunrin to gba owo lowo e too so pe nise lo gba oun loju.

Ninu oro Segun, o ni ojo karun-un, osu kewaa, odun to koja lo loo gba owo ohun ni Banki Access to wa lopopo Ibrahim Taiwo, n’Ilorin, eyi teeyan e to wa lorileede Amerika fi ranse si i. O so pe lojo buruku ohun, sadeedee lodaran naa gbe moto ti nomba e je MX 304 AAA waa ba oun, o ni koun wo oun loju, boun se wo o loju loun ko mo nnkan toun n se mo.

Lakooko yii lo so pe o pase foun pe koun loo gbe gbogbo owo to wa nile oun wa, oun si se bee. Aadojo egberun-un naira lo loun gbe fun un, atowo dola repete. A gbo pe o sise ibi naa pelu okunrin kan to n je Kayode eni to ti sa lo bayii. Olopaa to n soju ijoba, Ogbeni Saani Abdullahi so pe iwadii si n te siwaju lori esun naa, fun idi eyi, ki odaran afurasi naa si wa latimole olopaa digba ti won yoo fi pari igbejo lori esun naa.

Adajo Mercy Abikoye so pe oun fara mo oro ti olopaato n soju ijoba so, fun idi eyi, o pase pe ki won ju u satimole ogba ewon di ojo kerin, osu kefa ti igbejo mi-in yoo tun waye.


**{Legacy activities, comments etc counter: 743; topic series: 11; forum: MediaYoruba; associated: 11- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Adebimpe Atore E Lu Ogbeni Hausa Abdulraheem Amadu To N Sewo Ni Jibiti l’Osogbo: Owo Olopaa Ti Te Segun To N Se Gbaju-e



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn